Tuesday, 19 August 2014

E pele nibeyen o! Se eti gbo pe EGBON wa maa to de, akobi DADDY wa (Kolose 1:15,Rom.8:29 Heb.1:6) ti a ti nreti lati ojo yii wa, won ni awon ti sunmo itosi wa gan-an, lati wa ko wa lo si ILE(Jhn.14: 2-3), Sugbon won ni ki nso fun yin pe ki e ye eru yin wo daada,nitoripe gbogbo eni ti o ba di erukeru bi eyi ti o wa ninu IWE Galatia Ori 5 ese 19 si 21, ko ni le ba awon lo, ati pe ti awon ba ti de, awon ko nile duro de enikeni lati sese maa mura,nitorina e je ka mura de won,ka wo ise owo wa, kasi tun ona wa se. E jowo ba mi ranse yii si awon ara to ku. A ku ifoju sona o. Ki Oluwa muwa ye lati dele layo! Amin!!! Emi ni okan ninu awon molebi.AKU ISE ONI OO

No comments:

Post a Comment